M’Cheyne Bible Reading Plan
Ìbí Isaaki
21 Olúwa sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, Olúwa sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. 2 (A)Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un. 3 Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki. 4 (B)Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. 5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki.
6 Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.” 7 Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.”
A lé Hagari àti Iṣmaeli jáde
8 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá. 9 Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, 10 (C)ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”
11 Ọ̀rọ̀ náà sì ba Abrahamu lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sá à ni Iṣmaeli i ṣe. 12 (D)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀. 13 Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”
14 Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba.
15 Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. 16 Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún.
17 Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. 18 Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.”
19 Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
20 Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà. 21 Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
Májẹ̀mú ní Beerṣeba
22 (E)Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. 23 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.”
24 Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.”
25 Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.”
27 Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. 28 Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀. 29 Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”
30 Ó dalóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
31 (F)Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.
32 Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini. 33 Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé. 34 Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́.
Òwe àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà
20 (A)“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. 2 Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.
3 “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. 4 Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ 5 Wọ́n sì lọ.
“Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. 6 Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’
7 “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’
“Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’
8 (B)“Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’
9 “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan. 10 Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. 11 Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, 12 pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’
13 (C)“Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan. 14 Ó ní, Gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ. 15 Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’
16 (D)“Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”
Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀
17 (E)Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19 Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
Ẹ̀bẹ̀ ìyá
20 (F)(G) Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.
21 (H)Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”
Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”
22 (I)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”
23 (J)Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”
24 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí. 25 (K)Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba. 26 Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, 27 Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin. 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
Afọ́jú méjì ríran
29 (L)Bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jeriko sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn. 30 Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”
31 Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sókè sí i. “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”
32 Jesu dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”
33 Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”
34 Àánú wọn sì ṣe Jesu, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójúkan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
10 Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni:
Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah.
Sedekiah 2 Seraiah, Asariah, Jeremiah,
3 Paṣuri, Amariah, Malkiah,
4 Hattusi, Ṣebaniah, Malluki,
5 Harimu, Meremoti, Ọbadiah,
6 Daniẹli, Ginetoni, Baruku,
7 Meṣullamu, Abijah, Mijamini,
8 Maasiah, Bilgai àti Ṣemaiah.
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà.
9 Àwọn ọmọ Lefi:
Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli,
10 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah,
Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani,
11 Mika, Rehobu, Haṣabiah,
12 Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,
13 Hodiah, Bani àti Beninu.
14 Àwọn olórí àwọn ènìyàn:
Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani,
15 Bunni, Asgadi, Bebai.
16 Adonijah, Bigfai, Adini,
17 Ateri, Hesekiah, Assuri,
18 Hodiah, Haṣumu, Besai,
19 Harifu, Anatoti, Nebai,
20 Magpiaṣi, Meṣullamu, Hesiri
21 Meṣesabeli, Sadoku, Jaddua
22 Pelatiah, Hanani, Anaiah,
23 Hosea, Hananiah, Haṣubu,
24 Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,
25 Rehumu, Haṣabna, Maaseiah,
26 Ahijah, Hanani, Anani,
27 Malluki, Harimu, àti Baanah.
28 “Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé 29 gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.
30 “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.
31 “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.
32 “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: 33 Nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
34 “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.
35 “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.
36 “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
37 “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. 38 Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí inú ilé ìṣúra. 39 Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí.
“Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”
Paulu kọjá ní Makedonia àti Giriki
20 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia. 2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. 3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ. 4 Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiu ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.
A jí Eutiku dìde nínú òkú ní Troasi
5 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi. 6 Àwa sì ṣíkọ̀ láti Filipi lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Troasi ni ọjọ́ méje.
7 Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. 8 Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. 9 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10 Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ìdágbére Paulu sí àwọn Alàgbà Efesu
13 Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. 14 Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15 Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16 Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.
17 Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. 19 Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù: 20 Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. 21 Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.
22 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀: 23 Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi. 24 Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrín ẹni tí èmi tí ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́. 26 Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo. 27 Nítorí tí èmi kò fàsẹ́yìn láti sọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin. 28 Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà. 29 Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. 30 Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. 31 Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.
32 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́. 33 Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. 34 Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. 35 Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”
36 Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. 37 Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 38 Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.