M’Cheyne Bible Reading Plan
7 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. 2 Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. 3 Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. 4 Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”
5 Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.
6 Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún (600) nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. 7 (A)Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. 8 Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, 9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.
11 (B)Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. 12 Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
13 Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. 14 Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. 15 Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. 16 Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.
17 Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. 19 Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. 20 Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 21 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. 22 Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. 23 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.
24 Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).
Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkejì
7 (A)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
3 (B)“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
Béèrè, kànkùn, wá kiri
7 (C)“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? 10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? 12 Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.
Ọ̀nà tóóró àti ọnà gbòòrò
13 (D)“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
Igi àti èso rẹ̀
15 (E)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 (F)“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé
24 (G)“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
28 (H) Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, 29 Nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.
Esra wá sí Jerusalẹmu
7 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah, 2 Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, 3 ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraioti, 4 ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki, 5 ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olórí àlùfáà— 6 Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀. 7 Ní ọdún keje ọba Artasasta díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili náà gòkè wá sí Jerusalẹmu.
8 Ní oṣù karùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Esra dé sí Jerusalẹmu. 9 Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Babeli ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀. 10 Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli.
Ọba Artasasta kọ lẹ́tà sí Esra
11 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà ti ọba Artasasta fún àlùfáà Esra olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Israẹli:
12 Artasasta, ọba àwọn ọba,
Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run:
Àlàáfíà.
13 Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. 14 Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu. 15 Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, 16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu. 17 Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu.
18 Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín. 19 Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jerusalẹmu fún ìsìn nínú tẹmpili Ọlọ́run rẹ. 20 Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.
21 Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín 22 tó ọgọ́ọ̀rún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀. 23 Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹmpili Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbègbè ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀? 24 Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sísan owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.
25 Ìwọ Esra, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè Eufurate, gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà. 26 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.
27 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọlá wá sí ilé Olúwa ní Jerusalẹmu ní ọ̀nà yìí. 28 Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.
Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀
7 Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”
2 (A)Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. 3 (B)Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’
4 (C)“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. 5 (D)Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. 6 (E)Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 7 (F)Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ 8 (G)Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 (H)(I) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (J)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 (K)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (L)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (M)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (N)(O)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (P)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.
17 (Q)“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. 18 Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 19 (R)Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.
20 (S)“Ní àkókò náà ni a bí Mose, (ẹni tí ó dára ní ojú Ọlọ́run) ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. 21 (T)Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀. 22 A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.
23 (U)“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa: 25 Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26 Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? 28 Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’ 29 (V)Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30 (W)“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. 31 Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32 Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.
33 “Olúwa sì wí fún un pé, ‘bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34 Ní rí rí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, Mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’
35 (X)“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 36 (Y)Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.
37 (Z)“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 38 (AA)Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.
39 (AB)“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti; 40 (AC)Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41 (AD)Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:
“ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi
ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,
àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,
àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.
Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’
44 (AE)“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45 (AF)Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 46 (AG)Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 47 (AH)Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 (AI)“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.
Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?
ni Olúwa wí.
Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51 (AJ)“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! 52 Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa. 53 Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”
A sọ Stefanu ní òkúta pa
54 Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. 55 Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 56 Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”
57 Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, 58 wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
59 Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.