M’Cheyne Bible Reading Plan
Ìran Adamu títí dé ìran Noa
5 (A)Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu.
Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. 2 Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.
3 Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. 4 Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 5 Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.
6 Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùnún ọdún (105), ó bí Enoṣi. 7 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 8 Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.
9 Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kenani. 10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. 11 Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.
12 Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Mahalaleli: 13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 14 Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.
15 Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Jaredi. 16 Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17 Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.
18 Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Enoku. 19 Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20 Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dínméjìdínlógójì (962), ó sì kú.
21 Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Metusela. 22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 23 Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irínwó-dínmárùn-dínlógójì-ọdún (365). 24 (B)Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.
25 Nígbà tí Metusela pé igba ó-dínmẹ́tàlá ọdún (187) ní o bí Lameki. 26 Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rìn-dínméjì-dínlógún ọdún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27 Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó-dínmọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.
28 Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.” 30 Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ó-dínmárùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 31 Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó-dínmẹ́tàlélógún (777), ó sì kú.
32 Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
Ìwàásù orí òkè
5 (A)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. 2 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.
Ó wí pé:
3 (B)“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí,
nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
4 (C)Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí a ó tù wọ́n nínú.
5 (D)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,
nítorí wọn yóò jogún ayé.
6 (E)Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa
tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
7 Alábùkún fún ni àwọn aláàánú,
nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
8 (F)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
9 Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
10 (G)Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.
11 “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. 12 (H)Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.
Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀
13 (I)“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
14 (J)“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15 (K)Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.
Ìmúṣẹ òfin
17 “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18 (L)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19 (M)Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20 Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.
Ìpànìyàn
21 (N)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ 22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.
23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. 24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.
25 (O)“Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. 26 Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.
Panṣágà
27 (P)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ 28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.
Ìkọ̀sílẹ̀
31 (Q)“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ 32 Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.
Ìbúra
33 (R)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ 34 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. 35 Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. 36 Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. 37 Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.
Ojú fún ojú
38 (S)“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ 39 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. 40 Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. 41 Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. 42 Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.
Fẹ́ràn ọ̀tá rẹ
43 (T)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? 47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.
Lẹ́tà Tatenai sí Dariusi
5 (A)Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn. 2 Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” 4 Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?” 5 Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi. 7 Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:
Sí ọba Dariusi:
Àlàáfíà fún un yín.
8 Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńláńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.
9 A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?” 10 A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.
11 Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:
“Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli.
13 (B)“Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́. 14 Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀, 15 ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’
16 “Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”
17 Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.
Anania àti Safira
5 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan, 2 Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
3 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, Èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? 4 Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”
5 Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. 6 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.
7 Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. 8 Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?”
Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
9 Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”
10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
Àwọn aposteli wo ọ̀pọ̀ sàn
12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn aposteli
17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.
Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.
27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè. 28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”
29 Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! 30 (A)Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. 32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”
33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n. 34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. 35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. 37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”
40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.
41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. 42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìhìnrere náà pé Jesu ni Kristi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.