Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kronika 19-23

Jehu bá Jehoṣafati wí

19 Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu, Jehu aríran, ọmọ Hanani jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Ṣé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra Olúwa? Nítorí èyí, ìbínú Olúwa wà lórí wa. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà Aṣerah kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.”

Jehoṣafati yan àwọn onídàájọ́

Jehoṣafati sì ń gbé ní Jerusalẹmu ó sì jáde lọ padà láàrín àwọn ènìyàn láti Beerṣeba dé òkè ìlú Efraimu, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn. Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda. Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́. Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, Jehoṣafati yan díẹ̀ lára àwọn Lefi, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Israẹli si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jerusalẹmu. Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé. “Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù Olúwa. 10 Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń sàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, pa á láṣẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyí, ìwọ kì yóò sì jẹ̀bi.

11 “Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”

Jehoṣafati pa Moabu àti Amoni run

20 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati.

Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe, En-Gedi). Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a.

Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. O sì wí pé:

Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. (A)Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’

10 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. 11 Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní. 12 Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”

13 Gbogbo àwọn ọkùnrin Juda, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kéékèèkéé, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

14 Nígbà náà, ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jahasieli ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah ọmọ Lefi àti ọmọ Asafu, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrín àpéjọ ènìyàn.

15 Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jehoṣafati àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Juda àti Jerusalẹmu! Èyí ní ohun tí Olúwa sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí ogun náà kì í ṣe tiyín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni. 16 Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli. 17 Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”

18 Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa. 19 Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ọmọ Kohati àti àwọn ọmọ Kora sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.

20 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí aginjù Tekoa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jehoṣafati dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ mi, Juda àti ènìyàn Jerusalẹmu! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.” 21 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé:

“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,
    nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.”

22 Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n. 23 Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.

24 Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá. 25 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀. 26 Ní ọjọ́ kẹrin, wọn kó ara jọ pọ̀ ní Àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27 Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. 28 Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè.

29 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà. 30 Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká.

Òpin ìjọba Jehoṣafati

31 (B)Báyìí ni Jehoṣafati jẹ ọba lórí Juda. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùn-dínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. 32 Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Asa kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa. 33 Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lú, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkàn wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn.

34 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoṣafati, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jehu ọmọ Hanani, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Israẹli.

35 (C)Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati ọba Juda da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Ahasiah, ọba Israẹli, ẹni tí ó jẹ̀bi ìwà búburú. 36 Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan ọkọ̀ láti lọ sí Tarṣiṣi, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Esioni-Geberi. 37 Elieseri ọmọ Dodafahu ti Meraṣa sọtẹ́lẹ̀ sí Jehoṣafati, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, Olúwa yóò pa ohun ti ìwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.

Jehoramu ọba Juda

21 (D)Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.

Jehoramu Ọba Juda

Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli. (E)Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu. Ó ṣe búburú lójú Olúwa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dafidi kì í ṣe ìfẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dafidi run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.

Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. 10 Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda.

Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. 11 Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.

12 Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé:

“Èyí ní ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. 13 Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ. 14 Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn ńlá. 15 Ìwọ tìkára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ”

16 Olúwa ru ìbínú àwọn ará Filistini àti àwọn Arabia tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá àwọn ará Kuṣi sí Jehoramu. 17 Wọ́n dojú ìjà kọ Juda, wọ́n gbà á, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Ahasiah, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jehoramu ní yà pẹ̀lú ààrùn tí kò ṣe é wòsàn nínú ìfun. 19 Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí ààrùn náà ó sì kú nínú ìrora ńlá. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bu ọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.

20 (F)Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dafidi. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.

Ahasiah ọba Juda

22 (G)Àwọn ènìyàn Jerusalẹmu mú Ahasiah, ọmọ Jehoramu tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Arabia sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.

Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, Ọmọ ọmọbìnrin Omri.

Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀. Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́; Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria.

Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́.

(H)Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sápamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.

Ataliah àti Joaṣi

10 (I)Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Juda run. 11 Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu mú Joaṣi, ọmọkùnrin Ahasiah ó sì jí gbé lọ kúrò láàrín àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti ìyàwó àlùfáà Jehoiada jẹ́ arábìnrin Ahasiah. Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataliah, kí ó má ba à pa á. 12 Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú wọn ni ilé Ọlọ́run fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah ṣàkóso ilẹ̀ náà.

23 Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri. Wọ́n lọ sí gbogbo Juda, wọ́n sì pe àwọn ará Lefi àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Israẹli láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Gbogbo ìpéjọ náà dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run.

Jehoiada wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jẹ ọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn ìran Dafidi. Nísinsin yìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe: Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Lefi tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn. Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa. Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítorí tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó sọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn. Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”

Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti apata wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún. 10 Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà.

11 Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi ààmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”

12 Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa. 13 Ó sì wò, sì kíyèsi, ọba dúró ní ibùdó rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afùnpè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn. Nígbà náà ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”

14 Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé: “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé Olúwa.” 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Ẹnu Ẹṣin ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀.

16 Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. 17 Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.

18 Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ. 19 Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé.

20 Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, Àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́. 21 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀. Ìlú naà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí tí a pa Ataliah pẹ̀lú idà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.