Chronological
16 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn
ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
3 Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́
Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
4 Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́
kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
5 Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀
mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
6 Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀
nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.
7 Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,
yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.
8 Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo
ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀
ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i
ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.
11 Òdínwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
12 Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́
nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,
wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.
14 Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;
ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ
àti láti yan òye dípò o fàdákà!
17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,
ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,
agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.
19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú
jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,
ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye
ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
22 Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,
ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀
ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.
24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin
ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
25 Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn
ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26 Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀;
nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.
27 Ènìyàn búburú ń pète
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28 Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀
olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀
ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30 Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;
ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31 Adé ògo ni ewú orí jẹ́,
ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.
32 Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,
ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
33 A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,
ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
17 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn
ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,
yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3 Iná ni a fi fọ́ Fàdákà àti wúrà
Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi
òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,
ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó
ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
7 Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè,
bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
8 Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í,
ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.
Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
10 Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn
ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
11 Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,
ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12 Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ
jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13 Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre,
ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi
nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15 Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi,
Olúwa kórìíra méjèèjì.
16 Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,
níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,
arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
18 Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,
ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19 Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;
ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,
ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
21 Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn,
kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,
ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
23 Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
láti yí ìdájọ́ po.
24 Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú,
ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
25 Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀
àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
26 Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀,
tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,
ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́
àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
18 Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;
ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,
nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,
ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú
tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀
ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́
ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀
arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;
olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn
wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga
ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn
ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;
etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn
a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre
títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
18 Ìbò dídì máa ń parí ìjà
a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,
ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;
láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,
àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,
o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,
ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.