Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Oniwaasu 1-6

Asán ni ohun ayé

Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu:

“Asán inú asán!”
    oníwàásù náà wí pé,
“Asán inú asán!
    Gbogbo rẹ̀ asán ni.”

Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,
    lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?
Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,
    síbẹ̀ ayé dúró títí láé.
Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,
    ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ.
Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù,
    Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,
a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.
Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun,
    síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún.
Níbi tí àwọn odò ti wá,
    níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.
Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,
    ju èyí tí ẹnu le è sọ.
Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn,
    bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.
Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn
    òun ni a ó tún máa ṣe padà
    kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.
10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé,
    “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”?
Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́,
    o ti wà ṣáájú tiwa.
11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú
    bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún
ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀
    lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.

Asán ni ọgbọ́n ènìyàn

12 Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. 13 Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn: 14 Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

15 Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,
    ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.

16 Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” 17 Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

18 Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,
    bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.

Ìgbádùn

Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

(A)Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. (B)Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

10 Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.
    N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.
Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,
    èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.
11 Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe
    àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:
gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni
    gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;
ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.

12 Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,
    àti ìsínwín àti àìgbọ́n
kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe
    ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.
13 Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀
    gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.
14 Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,
    nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,
ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀
    wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.
15 Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,
    “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú
kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”
    Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,
    “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”
16 Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;
    gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.
Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

Asán ni iṣẹ́ ṣíṣe

17 Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18 Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19 Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. 20 Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. 21 Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnrarẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22 Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23 Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

24 (C)Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25 Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? 26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

Àkókò àti ìgbà wà fún ohun gbogbo

Àsìkò wà fún ohun gbogbo,
    àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.

Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,
    ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá
    ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín
    ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó
Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ
    ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn
Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri
    ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán
    ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀
Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra
ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀? 10 Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. 12 Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. 13 Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́. 14 Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.

15 Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,
    ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,
    Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀.

16 Mo sì tún rí ohun mìíràn ní

abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,
    òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀.

17 Mo wí nínú ọkàn mi,

“Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́
    olódodo àti ènìyàn búburú,
nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,
    àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”

18 Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. 19 Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. 20 Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí. 21 Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?”

22 Nígbà náà, ni mo wá rí i wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kò sí!

Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́

Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,

mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò
    sì ní olùtùnú kankan,
agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,
    wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú
    tí wọ́n sì ti lọ,
ó sàn fún wọn ju àwọn
    tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju
    àwọn méjèèjì lọ:
ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú
    tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.

Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò
    ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,
    àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:

Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;
    kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí
kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,
    síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,
    àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”
Eléyìí náà asán ni
    iṣẹ́ òsì!

Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,
    nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn:
10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,
    ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,
ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú
    tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!
11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.
    Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,
    àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,
ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.

Asán ni ipò gíga

13 Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn, 14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. 15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. 16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Dídúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run

Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.

Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ,
    má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run
Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run
    ìwọ sì wà ní ayé,
    nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.

Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Asán ni ọrọ̀ jẹ́

Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10 Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,
    ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn
    pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

11 Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i
    náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i
Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,
    kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?

12 Oorun alágbàṣe a máa dùn,
    yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
    kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.

13 Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn

ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.
14     Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
    kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.
15 Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
    bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
    tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16 Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá:

Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
    kí wá ni èrè tí ó jẹ
    nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
17 Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,
    pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18 Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. 19 Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí. 20 Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.

Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.

Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́ọ̀rún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni
    síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí
Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní
    lórí aṣiwèrè?
Kí ni èrè tálákà ènìyàn
    nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?
Ohun tí ojú rí sàn
    ju ìfẹnuwákiri lọ
Asán ni eléyìí pẹ̀lú
    ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

10 Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,
    ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;
kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì
    pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ
11 Ọ̀rọ̀ púpọ̀,
    kì í ní ìtumọ̀
    èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

12 Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.