Chronological
Abijah ọba Juda
15 (A)Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Jeroboamu ọmọ Nebati, Abijah jẹ ọba lórí Juda, 2 ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́ta ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.
3 Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. 4 Ṣùgbọ́n, nítorí i Dafidi Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jerusalẹmu nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jẹ ọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀. 5 Nítorí tí Dafidi ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pàṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Uriah ará Hiti.
6 Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní gbogbo ọjọ́ ayé Abijah. 7 Ní ti ìyókù ìṣe Abijah, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ogun sì wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. 8 (B)Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Asa ọba Juda
9 Ní ogún ọdún Jeroboamu ọba Israẹli, Asa jẹ ọba lórí Juda, 10 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ńlá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.
11 Asa sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. 12 Ó sì mú àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò. 13 (C)Ó sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. 14 Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Asa pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo. 15 Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa.
16 Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. 17 Baaṣa, ọba Israẹli sì gòkè lọ sí Juda, ó sì kọ́ Rama láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba lọ.
18 Nígbà náà ni Asa mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Beni-Hadadi ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni ọba Siria tí ó ń gbé ní Damasku. 19 Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrín èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Baaṣa, ọba Israẹli, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”
20 Beni-Hadadi gba ti Asa ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Israẹli. Ó sì ṣẹ́gun Ijoni, Dani àti Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo Kinnereti pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. 21 Nígbà tí Baaṣa sì gbọ́ èyí, ó sì ṣíwọ́ kíkọ́ Rama, ó sì lọ kúrò sí Tirsa. 22 Nígbà náà ni Asa ọba kéde ká gbogbo Juda, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta Rama kúrò àti igi rẹ̀, tí Baaṣa fi kọ́lé. Asa ọba sì fi wọ́n kọ́ Geba ti Benjamini àti Mispa.
23 (D)Ní ti ìyókù gbogbo ìṣe Asa, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, ààrùn ṣe é ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 24 (E)Asa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Abijah ọba Juda
13 (A)Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Jeroboamu, Abijah di ọba Juda. 2 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah.
Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. 3 Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.
4 Abijah dúró lórí òkè Ṣemaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi! 5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀? 6 Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀. 7 Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnrarẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.
8 “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín. 9 Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run.
10 “Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. 11 Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 12 Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”
13 Nísinsin yìí, Jeroboamu ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà níwájú Juda, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn. 14 Nígbà tí Juda sì bojú wo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwájú àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe Olúwa, àwọn àlùfáà sì fun ìpè. 15 Olúkúlùkù, ọkùnrin Juda sì fún ìpè ogun, ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Juda sì ti fun ìpè ogun, ni Ọlọ́run kọlu Jeroboamu àti gbogbo Israẹli níwájú Abijah àti Juda. 16 Àwọn ọmọ Israẹli sálọ kúrò níwájú Juda, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́. 17 Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli. 18 Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Juda sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn.
19 Abijah sì lépa Jeroboamu, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Beteli pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣana pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Efroni pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀. 20 Bẹ́ẹ̀ ní Jeroboamu kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Abijah. Olúwa sì lù ú ó sì kú.
21 Abijah sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́tàlá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìn-dínlógún.
22 Àti ìyókù ìṣe Abijah, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀, wòlíì Iddo.
Asa ọba Juda
14 Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀-èdè wà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá.
2 Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 3 Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn ère Aṣerah bolẹ̀. 4 Ó pa á láṣẹ fún Juda láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ. 5 Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Juda. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀. 6 Ó mọ àwọn ìlú ààbò ti Juda, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lú rẹ̀ nígbà náà, nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi.
7 “Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí” Ó wí fún Juda, “Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu-ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.
8 Asa ní àwọn ọmọ-ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Juda. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Benjamini wọ́n dira pẹ̀lú àwọn apata kéékèèkéé àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin.
9 Sera ará Etiopia yàn láti dojúkọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Meraṣa. 10 Asa jáde lọ láti lọ bá a. Wọ́n sì mú ibi ogun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Sefata lẹ́bàá Meraṣa.
11 Nígbà náà, Asa ké pe Olúwa Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “Olúwa kò sí ẹnìkan bí rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́ láti dójú kọ alágbára. Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.”
12 Olúwa lu àwọn ará Kuṣi bolẹ̀ níwájú Asa àti Juda. Àwọn ará Kuṣi sálọ. 13 Asa àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gerari. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kuṣi ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. Wọn rún wọn mọ́lẹ̀ níwájú Olúwa àti ọmọ-ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Juda kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun. 14 Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gerari, nítorí tí ìpayà Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn. Wọ́n kó gbogbo ìkógun àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀. 15 Wọ́n kọlu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jerusalẹmu.
Àtúnṣe asà
15 Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Asariah ọmọ Odedi. 2 Ó jáde lọ bá Asa, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Asa, àti gbogbo Juda àti Benjamini. Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 3 Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Israẹli ti wà láì sin Ọlọ́run òtítọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láìní òfin. 4 Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn. 5 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá 6 Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlú kan sí òmíràn nítorí Ọlọ́run ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú. 7 Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì ṣe ṣàárẹ̀. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ.”
8 Nígbà tí Asa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Asariah ọmọ Odedi wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó sì mú gbogbo ohun ìríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda àti Benjamini àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní orí òkè Efraimu. Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé Olúwa.
9 Nígbà naà, ó pe gbogbo Juda àti Benjamini jọ àti àwọn ènìyàn láti Efraimu, Manase àti Simeoni tí ó ti ṣe àtìpó ní àárín wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Israẹli nígbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
10 Wọ́n péjọ sí Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹ́ẹ̀dógún ti ìjọba Asa. 11 Ní àkókò yìí, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa ọgọ́rùn-ún méje akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkógun tí wọ́n ti kó padà. 12 Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn. 13 Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin. 14 Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè. 15 Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri.
16 (B)Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. 17 Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Israẹli; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Asa wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. 18 Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.
19 Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùn-dínlógójì ti ìjọba Asa.
Ìgbẹ̀yìn ọdún asà
16 Ní ọdún kẹrìn-dínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.
2 Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, 3 “Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
4 Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. 5 Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. 6 Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.
7 Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. 8 Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. 9 Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”
10 Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
11 Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 12 (C)Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. 13 Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, 14 Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.