Chronological
Èròǹgbà àti kókó-ọ̀rọ̀
1 Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.
2 Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,
Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
3 Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,
àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
4 láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,
ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
5 Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,
sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
6 Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,
àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.
7 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ṣàfẹ́rí ọgbọ́n
8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,
má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ
àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,
má ṣe gbà fún wọn.
11 Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;
jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,
jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
12 Jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,
àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13 A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí
a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa;
14 Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,
a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà”
15 Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,
má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;
16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,
wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
17 Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀,
ní ojú ẹyẹ!
18 Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.
Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà
19 Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;
yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.
Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀
20 (A)Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó
ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;
21 Láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde
Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:
22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?
Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?
Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,
Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín
kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.
24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè
kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,
25 Níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,
tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,
26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;
èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.
27 Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,
Nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,
nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.
28 “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;
wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
29 Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀
tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.
30 Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi
tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
31 Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn
wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún
32 Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n
ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
33 Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu
yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
Èrè ìwà rere tí ọgbọ́n ń mú wá
2 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,
tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n
tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,
tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà
tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,
ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,
láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá
7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,
Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
8 ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́
Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
9 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,
àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ
ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ
11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́
òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.
12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin
láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,
tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́
tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.
16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,
àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀
tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú
ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.
20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere
kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà
àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà
a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.
Àwọn àǹfààní ọgbọ́n mìíràn
3 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,
kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
4 (B)Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
7 (C)Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
àti okun fún àwọn egungun rẹ.
9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,
pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ
10 Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11 (D)Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”
nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
34 (E)Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,
ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.