Book of Common Prayer
Adúra ti Dafidi.
86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,
nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ, Olúwa,
ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
Àlá Jakọbu ní Beteli
10 Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11 Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12 (A)Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13 (B)Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 14 (C)Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”
16 Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”
Jesu pe Filipi àti Natanaeli
43 (A)Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
44 Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. 45 (B)Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”
46 (C)Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?”
Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”
47 Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”
48 Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”
Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”
49 (D)Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”
50 Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.” 51 (E)Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
Sí àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin
5 Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn: 2 Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. 3 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. 4 Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.
5 (A)Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,
“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7 (B)Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.
8 Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. 9 Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.
10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. 11 Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.