Book of Common Prayer
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
Orin fún ìgòkè.
132 Olúwa, rántí Dafidi
nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
2 Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,
tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé.
3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi:
4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5 Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,
ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu.
6 Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
8 Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
11 (A)Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi:
Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:
ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi
133 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.
2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀;
3 Bí ìrì Hermoni
tí o sàn sórí òkè Sioni.
Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,
àní ìyè láéláé.
Orin ìgòkè.
134 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,
kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.
3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,
kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
135 Ẹ yin Olúwa.
Ẹ yin orúkọ Olúwa;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
ní ọ̀run àti ní ayé,
ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14 (B)Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,
tí ń gbé Jerusalẹmu.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé Jobu
1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú, 2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. 3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. 5 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Ìdánwò Jobu àkọ́kọ́
6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. 7 Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”
Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọ-síwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
8 Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”
9 Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” 10 “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. 11 Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”
12 Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.
13 Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, 14 oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé: “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn; 15 Àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
16 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
17 Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
18 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. 19 Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńláńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21 wí pé:
“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,
ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.
Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,
ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
22 Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
Filipi àti ìwẹ̀fà Itiopia
26 Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.” 27 Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn, 28 Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah. 29 Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”
31 Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.
32 (A)Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:
“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;
àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.
33 Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún:
Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?
Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”
34 Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35 Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìhìnrere ti Jesu fún un.
36 Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?” 37 Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni.” 38 Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. 39 Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. 40 Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìhìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.
Jesu rin lórí omi
16 (A)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.
22 Ní ọjọ́ kejì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní òdìkejì Òkun rí i pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ. 23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberia wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́; 24 Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jesu tàbí ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kapernaumu, wọ́n ń wá Jesu.
Jesu oúnjẹ ìyè
25 Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apá kejì Òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rabbi, nígbà wo ni ìwọ wá síhìn-ín yìí?”
26 Jesu dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́ ààmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà. 27 (B)Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ayé àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.