Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 101

Ti Dafidi. Saamu.

101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
    sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
    ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?

Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
    pẹ̀lú àyà pípé.
Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
    iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.

    Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
    Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
    òun ní èmi yóò gé kúrò
ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
    òun ní èmi kì yóò faradà fún.

Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
    kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
    òun ni yóò máa sìn mí.

Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
    kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
    gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
    kúrò ní ìlú Olúwa.

Saamu 109:1-30

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún
    Má ṣe dákẹ́
Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
    ti ya ẹnu wọn sí mi
    wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
    wọ́n bá mi jà láìnídìí
Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
    ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
    àti ìríra fún ìfẹ́ mi.

Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
    jẹ́ kí àwọn olùfisùn
    dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
    kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
(A)Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú
    kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀
Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
    kí aya rẹ̀ sì di opó
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
    kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
    jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
    tàbí kí wọn káàánú lórí
    àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
    kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
    ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa
    Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
    kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
    ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
    kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
    bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní
    ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
    àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
    ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ
    Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
    àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
    mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
    ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 (B)Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
    nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
    wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre;
    Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
    kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.

30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
    ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín

Saamu 119:121-144

Olórin pa òfin Olúwa mọ́

121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
    má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
    má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
    fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
    kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
    kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
    nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
    ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
    èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́

129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
    nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
    ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
    nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
    bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
    tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
    má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
    kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
    kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
    nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
    ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
    wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
    ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
    èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
    òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
    fún mi ní òye kí èmi lè yè.

Onidajọ 13:15-24

15 Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”

16 Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)

17 Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”

18 Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.” 19 Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan. 20 Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli Olúwa gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀. 21 Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni.

22 Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”

23 Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”

24 (A)Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un.

Ìṣe àwọn Aposteli 6

Yíyan àwọn méje

Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.

A mú Stefanu

Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ ààmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, 10 ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11 Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Stefanu ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọ́run.”

12 Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. 13 Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. 14 Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.”

15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.

Johanu 4:1-26

Jesu sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Samaria

(A)Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.

(B)Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. (C)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.

Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.

(D)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

10 (E)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”

13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (F)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

15 (G)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (H)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (I)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 (J)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (K)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (L)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 (M)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.