Book of Common Prayer
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
8 (B)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”
12 Nígbà tí wọn kéré níye,
wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
láti ìjọba kan sí èkejì.
14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”
16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
23 Israẹli wá sí Ejibiti;
Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
ó sì mú wọn lágbára jù
àwọn ọ̀tá wọn lọ
25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀
àti Aaroni tí ó ti yàn
27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
ó pa ẹja wọn.
30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32 Ó sọ òjò di yìnyín,
àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
àti kòkòrò ní àìníye,
35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
ààyò gbogbo ipá wọn.
37 Ó mú Israẹli jáde
ti òun ti fàdákà àti wúrà,
nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.
39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.
42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìgbéyàwó Samsoni
14 Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. 2 Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.”
3 Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?”
Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” 4 (Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.)
5 Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 6 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀. 7 Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Samsoni sì yọ́ sí i.
8 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, 9 ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.
10 Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. 11 Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.
12 Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. 13 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”
Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”
14 Ó dáhùn pé,
“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;
láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”
Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà.
15 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”
16 Nígbà náà ni ìyàwó Samsoni ṣubú lé e láyà, ó sì sọkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! O kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
“Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.” 17 Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
18 Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé,
“Kí ni ó dùn ju oyin lọ?
Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?”
Samsoni dá wọn lóhùn pé,
“Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀,
ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”
19 Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.
15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.
Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀
7 Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”
2 (A)Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. 3 (B)Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’
4 (C)“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. 5 (D)Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. 6 (E)Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 7 (F)Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ 8 (G)Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 (H)(I) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (J)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 (K)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (L)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (M)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (N)(O)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (P)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pẹ̀lú Jesu
27 Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”
28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, 29 (A)“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” 30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.
31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”
32 (B)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”
33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”
34 (C)Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35 (D)Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. 36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. 37 (E)Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. 38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”
Ọ̀pọ̀ ara Samaria gbàgbọ́
39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” 40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
42 (F)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.