Book of Common Prayer
Maskili ti Etani ará Esra.
89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
3 (A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
“Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (B)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (C)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán:
33 Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37 (D)A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela.
38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;
ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni ààmì òróró rẹ.
39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;
ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku
40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀
ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;
ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;
ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,
ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,
ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.
46 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?
Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?
Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
49 Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
50 Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
51 Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa,
tí wọn gan ipasẹ̀ Ẹni ààmì òróró rẹ.
52 Olùbùkún ní Olúwa títí láé.
Àmín àti Àmín.
Jefta àti Efraimu
12 Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”
2 Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. 3 Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”
4 Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.” 5 Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” 6 wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣíbólétì.’ ” Tí ó bá ní, “Síbólé tì,” torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin.
7 Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi.
Àwọn aposteli wo ọ̀pọ̀ sàn
12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn aposteli
17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.
Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.
Jesu kọ́ Nikodemu
3 (A)Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù: 2 (B)Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
3 (C)Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”
4 Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?
5 (D)Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. 6 (E)Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. 7 Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ 8 (F)Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”
9 Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”
10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 11 (G)Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12 Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13 (H)Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14 (I)Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
16 (J)“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17 (K)Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. 18 Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́. 19 (L)Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 21 (M)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.