Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 75-76

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.

75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
    a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
    àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
    Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
    Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
    Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
    Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
    ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
    tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
    Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
    ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
    àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
    Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.

76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
    orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
    ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
    asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

Ìwọ ni ògo àti ọlá
    Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
    wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
    tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
    àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
    Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
    ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
    bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
    ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.

11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
    kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
    mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
    àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

Saamu 27

Ti Dafidi.

27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
    láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
    ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
    nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
    òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
    yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
    ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
    èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
    ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
“Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
    Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
    má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
    ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
    háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
    Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
    nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
    nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
    wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
    èmi yóò rí ìre Olúwa
    ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
    kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
    àní dúró de Olúwa.

Onidajọ 5:19-31

19 “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;
    àwọn ọba Kenaani jà
ní Taanaki ní etí odo Megido,
    ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.
20 Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá
    láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,
    odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.
    Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára!
22 Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
    nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
23 ‘Ẹ fi Merosi bú’ ni angẹli Olúwa wí.
    ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
    láti dojúkọ àwọn alágbára.’

24 “Ìbùkún ni fún Jaeli,
    aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
    ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.
25 Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
    ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.
26 Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,
    ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,
òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,
    ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin.
27 Ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀
    ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀,
ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;
    níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.

28 “Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé,
    ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,
‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?
    Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’
29 Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;
    àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,
30 ‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:
    ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,
fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,
    ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,
àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,
    gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’

31 (A)“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!
    Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,
    nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”

Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.

Ìṣe àwọn Aposteli 2:22-36

22 “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti ààmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú. 23 Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á. 24 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú. 25 (A)Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé:

“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí,
    nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,
    a kì ó ṣí mi ní ipò.
26 Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:
    pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.
27 Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.
28 Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,
    ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

29 “Ará, èmí lè sọ fún yín pẹ̀lú ìgboyà pé Dafidi baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30 (B)Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 31 (C)Ní rí rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kristi, pé a kò fi ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́. 32 Jesu náà yìí ni Ọlọ́run ti jí dìde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí. 33 A ti gbéga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsin yìí síta. 34 (D)Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wí pé,

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
35 títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

36 “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jesu náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, ṣe Olúwa àti Kristi.”

Matiu 28:11-20

Àwọn olùṣọ́ ròyìn

11 (A)Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14 Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” 15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.

Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

16 (B)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 (C)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.