Book of Common Prayer
148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
2 Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
3 Ẹ fi ìyìn fún un,
oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
4 Ẹ fi ìyìn fún un,
ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
àti ẹ̀yin ibú Òkun
8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.
2 Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
ayọ̀ nínú ọba wọn.
3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
4 Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
113 Ẹ máa yin Olúwa.
Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
2 Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
4 Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5 Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
tí ó gbé ní ibi gíga.
6 Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7 Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
8 Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹ yin Olúwa.
114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2 Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
3 (A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,
ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
6 (B)Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi
Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò
11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù
12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,
ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;
ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14 Olúwa ni agbára àti orin mi;
ó sì di ìgbàlà mi.
15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
“Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;
ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18 Olúwa bá mi wí gidigidi,
ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
ìwọ sì di ìgbàlà mi.
22 (C)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
25 (D)Olúwa, gbà wá;
Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Àjọ ìrékọjá
12 (A)Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni ni ilẹ̀ Ejibiti pé, 2 “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín. 3 Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan. 4 Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn tiwọn jẹ láti ṣe òdínwọ̀n irú ọ̀dọ́-àgùntàn tiwọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ. 5 Ọ̀dọ́-àgùntàn tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́. 6 Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mọ́júmọ́. 7 Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 8 Ní òru ọjọ́ kan náà, wọn yóò jẹ ẹran tí a ti fi iná sun, pẹ̀lú ewé ewúro àti àkàrà aláìwú. 9 Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà. 10 Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí ó bá ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná. 11 Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ́ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.
12 “Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni Èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Ejibiti kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àti ènìyàn, àti ẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ejibiti. Èmi ni Olúwa.” 13 Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ ààmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, Èmi yóò ré e yín kọjá. Ààrùn kan kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Ejibiti láti pa wọ́n run.
14 (B)“Ọjọ́ òní ni yóò sì máa ṣe ọjọ́ ìrántí fún yín, ẹ́yin yóò sì máa láàrín àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe ní àjọ fún Olúwa; ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé.
9 Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
Ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
Ọ̀rọ̀ di ẹran-ara
1 (A)Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. 2 Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. 3 (B)Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. 4 (C)Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, 5 (D)ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.
6 (E)Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu. 7 Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. 8 Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà.
9 (F)Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé. 10 Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n. 11 Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á. 12 (G)Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run; 13 (H)Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
14 (I)Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
15 (J)Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 16 (K)Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 17 (L)Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá. 18 (M)Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbásepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.
Ní ojú ọnà sí Emmausi
13 Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. 14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 16 (A)Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.
17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”
Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
19 (B)Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, 20 Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. 21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. 22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: 23 Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. 24 (C)Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”
25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: 26 Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” 27 (D)Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
28 (E)Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. 29 Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
30 (F)Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. 31 Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú 32 Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, 34 (G)Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
Jesu fi ara han àwọn Aposteli
19 (A)Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20 Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.
21 (B)Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 22 (C)Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́! 23 (D)Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.