Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 95

95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
    orin àti ìyìn.

Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
    ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
    àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
    Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
(A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
    àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

    Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
    àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
    tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
    mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
    ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”

Saamu 22

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
    àní sí igbe ìkérora mi?
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
    wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
    ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11 Má ṣe jìnnà sí mi,
    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
    àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
    tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
    gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
    tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
    ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
    ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16 Àwọn ajá yí mi ká;
    ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
    Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
    àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
    àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
    Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
    àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
    Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
    ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
    ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
    gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
    àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
    a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
    sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
    wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

Saamu 40

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
Ó fà mí yọ gòkè
    láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
    tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
    ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
    wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
    láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
    èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
    ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
    èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
    kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,
    fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
    kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.
12 Nítorí pé àìníye ibi
    ni ó yí mi káàkiri,
ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
    títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
    àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13 (B)Jẹ́ kí ó wù ọ́,
    ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
    Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì
    ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú
    àwọn tí ń wá ọkàn mi
láti parun:
    jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn
kí a sì dójútì wọ́n,
    àwọn tí ń wá ìpalára mi.
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
    ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
    kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
    kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
    “Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
    tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
    Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
    ìwọ Ọlọ́run mi.

Ẹkun Jeremiah 3:1-9

Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú
    pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn
    nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi
    síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.

Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó
    ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká
    pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,
    bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;
    ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,
    ó kọ àdúrà mi.
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;
    ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

Ẹkun Jeremiah 3:19-33

19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,
    ìkorò àti ìbànújẹ́.
20 Mo ṣèrántí wọn,
    ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn
    àti nítorí náà ní mo nírètí.

22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,
    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;
    títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;
    nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,
    sí àwọn tí ó ń wá a.
26 Ó dára kí a ní sùúrù
    fún ìgbàlà Olúwa.
27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà
    nígbà tí ó wà ní èwe.

28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,
    nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku—
    ìrètí sì lè wà.
30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,
    sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31 Ènìyàn kò di ìtanù
    lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32 Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,
    nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33 Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá
    tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

1 Peteru 1:10-20

10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. 11 Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. 12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.

Ẹ jẹ́ mímọ́

13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16 (A)Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín,

Johanu 13:36-38

36 (A)Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?”

Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.”

37 (B)Peteru wí fún un pé, “Olúwa èéṣe tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ lẹ́hìn nísinsin yìí? Èmi ó fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”

38 Jesu dalóhùn wí pé, “Ìwọ ó ha fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, àkùkọ kì yóò kọ, kí ìwọ kí ó tó ṣẹ́ mi nígbà mẹ́ta!

Johanu 19:38-42

Ìsìnkú Jesu

38 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò: Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ. 39 (B)Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún lítà. 40 (C)Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn. 41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí. 42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.