Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 146-149

146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
    Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
    àní, ọmọ ènìyàn,
    lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
    Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
Ìbùkún ni fún ẹni tí
    Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
    tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
    òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
    ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
    tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
    Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
    Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
    ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
    ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
    Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
    ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
    Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
    ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
    ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
    òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
    fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
    ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
    ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
    àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
    bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
    yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
    Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
    òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
    ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
    ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
    ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
    ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
    àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
    wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Eksodu 13:3-10

Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa. Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. 10 Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.

1 Kọrinti 15:41-50

41 Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

42 (A)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́: 43 A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára. 44 A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.

Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ. 45 (B)Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a;” Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè. 46 Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí. 47 Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni. 48 Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run. 49 Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.

50 Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.

Matiu 28:16-20

Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

16 (A)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 (B)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.