Book of Common Prayer
Orin fún ìgòkè.
120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
ó sì dá mi lóhùn
2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3 Kí ni kí a fi fún ọ?
Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kedari!
6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.
Orin fún ìgòkè.
121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá
Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
yóò pa ọkàn rẹ mọ́
8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
ìwọ Jerusalẹmu.
3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
Orin fún ìgòkè.
123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
2 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
3 Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
4 Nígbà náà ni omi
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
5 Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
okùn já àwa sì yọ.
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Orin fún ìgòkè.
125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
4 Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.
Orin fún ìgòkè.
126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,
bí ìṣàn omi ní gúúsù.
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
yóò fi ayọ̀ ka.
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
yóò sì ru ìtí rẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
ojú kì yóò tì wọ́n,
ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
Bíríkì sísun láìsí koríko gbígbẹ
5 Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”
2 Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”
3 Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.”
4 Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.” 5 Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”
6 Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn. 7 “Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn. 8 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’ 9 Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”
10 Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Farao sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́. 11 Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ” 12 Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Ejibiti láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì. 13 Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti ṣe fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.” 14 Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”
15 Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Israẹli tọ Farao lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí? 16 Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”
17 Farao sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ní ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Olúwa.’ 18 Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”
19 Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.” 20 Ní ìgbà tí wọ́n kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao wọ́n rí Mose àti Aaroni tí ó dúró láti pàdé wọn. 21 Wọn sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Farao àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni idà láti fi pa wá.”
Ọlọ́run ṣe ìlérí ìgbàsílẹ̀ fún Israẹli
22 Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi? 23 Láti ìgbà ti mo ti tọ Farao lọ láti bá a sọ̀rọ̀ ni orúkọ Rẹ ni Ó ti mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni Ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn Rẹ sílẹ̀ rárá.”
6 (A)Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
20 (A)Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21 (B)A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,
“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí.
22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí ààmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”
Ètò ìsìn lẹ́sẹẹsẹ
26 (C)Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró. 27 Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbí bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀, 28 Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
29 Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ. 30 Bí a bá sì fi ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́. 31 Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú. 32 Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.
39 Nítorí náà ará, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dánilẹ́kun láti fi èdè fọ̀. 40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.
Okùnfà ẹ̀ṣẹ̀
42 (A)“Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú Òkun. 43 Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o ṣe akéwọ́ lọ sí ibi ìyè, ju o ní ọwọ́ méjèèjì kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì, sínú iná àjóòkú. 44 Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nà án kì í kú. 45 Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnù, ó sàn kí ó di akesẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹsẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì. 46 Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nà án kì í sì í ku. 47 Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì. 48 Níbi ti
“ ‘kòkòrò wọn kì í kú,
tí iná kì í sì í kú.’
49 (B)Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò.
50 (C)“Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mú un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.