Book of Common Prayer
Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa
102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
2 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
3 Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
egungun mi sì jóná bí ààrò
4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
5 Nítorí ohùn ìkérora mi,
egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8 Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
èmi sì rọ bí koríko.
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
“Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6 Fi etí sí igbe mi,
nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Saamu ti Dafidi.
143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
fetísí igbe mi fún àánú;
nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2 (A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ń lépa mi,
ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
10 Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni
jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;
wọ́n da eruku sí orí wọn
wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu
ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.
11 Ojú mi kọ̀ láti sọkún,
mo ń jẹ ìrora nínú mi,
mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀
nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,
nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú
ní òpópó ìlú.
12 Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,
“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó
bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe
ní àwọn òpópónà ìlú,
bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò
láti ọwọ́ ìyá wọn.
13 Kí ni mo le sọ fún ọ?
Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,
Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,
kí n lè tù ọ́ nínú,
Ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.
Ta ni yóò wò ọ́ sàn?
14 Ìran àwọn wòlíì rẹ
jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.
15 Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ
pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn
sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní
àṣepé ẹwà,
ìdùnnú gbogbo ayé?”
16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn
gbòòrò sí ọ;
wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke
wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.
Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;
tí a sì wá láti rí.”
17 Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;
ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.
Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,
ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,
ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.
18 Ọkàn àwọn ènìyàn
kígbe jáde sí Olúwa.
Odi ọmọbìnrin Sioni,
jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò
ní ọ̀sán àti òru;
má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,
ojú rẹ fún ìsinmi.
Oúnjẹ òrìṣà àti oúnjẹ alẹ́ Olúwa
14 (A)Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnrarẹ̀ ohun tí mo sọ. 16 (B)Ǹjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17 Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo.
27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.
Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
12 (A)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?”
13 Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 14 Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 15 Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.”
16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.
17 (B)Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀. 18 Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”
19 Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”
20 Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. 21 Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
22 (C)(D) Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”
23 (E)Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.
24 (F)Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. 25 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.