Add parallel Print Page Options

15 “Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

Read full chapter

18 (A)“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá.

Read full chapter

Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan nínú rẹ̀. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.’ ”

Read full chapter

17 (A)Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá; 21 pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá. 22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín. 23 Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀. 24 Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25 Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

Read full chapter

Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Ejibiti: kí ẹ bá à lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Ejibiti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Kí a má sì ṣe rí àkàrà wíwú ní ọ̀dọ̀ rẹ nínú ilẹ̀ rẹ ní ijọ́ méje. Kí ìwọ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹ́kù nínú ẹran tí ìwọ ó fi rú ẹbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kejì.

Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín. Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

Read full chapter