Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.
45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
3 Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
4 Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà
lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
5 Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.
48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2 (A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
ní ìlú ọba ńlá.
3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5 Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ní ìlú Ọlọ́run wa,
Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.
9 Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
nítorí ìdájọ́ rẹ.
12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
Dafidi, Nabali àti Abigaili
25 Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.
2 Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. 3 Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nabali, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Abigaili; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kalebu ni òun jẹ́.
4 Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀. 5 Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi. 6 Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!
7 “ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli. 8 Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojúrere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àsè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti fún Dafidi ọmọ rẹ.’ ”
9 Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nabali gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì sinmi.
10 Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀. 11 Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”
12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 13 Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù.
14 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Abigaili aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dafidi rán oníṣẹ́ láti aginjù wá láti kí olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn. 15 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko. 16 Odi ni wọ́n sá à jásí fún wa lọ́sàn án, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn. 17 Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Beliali tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”
18 Abigaili sì yára, ó sì mú igbá ìṣù àkàrà àti ìgò ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, tí a ti ṣè, àti òṣùwọ̀n àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dìwọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 19 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Máa lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” Ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nabali baálé rẹ̀.
20 Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn. 21 Dafidi sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyí tí i ṣe ti eléyìí ní aginjù, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni ó sì fi ibi san ìre fún mi yìí. 22 Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”
Ní Ikoniomu
14 Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, 2 Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. 3 Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. 4 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. 5 Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, 6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. 7 Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere.
Ní Lysra àti Dabe
8 Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. 9 Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. 10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” 12 Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. 13 Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: 15 (A)“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. 17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” 18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.
Àtùpà lórí ọ̀pá fìtílà
21 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22 (B)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (C)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 (D)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. 25 (E)Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
Òwe irúgbìn tó ń dàgbà
26 (F)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
Òwe musitadi
30 (G)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (H)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.