Book of Common Prayer
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7 Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
7 A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.” 8 Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.
9 Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín-yìí!” 10 Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. 11 Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?”
Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”
12 Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?”
Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”
13 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.”
14 Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sápamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.
Àwọn ará Sifi dalẹ̀ Dafidi
15 Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. 16 Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. 17 Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” 18 Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀.
Ìyìn fún Ọlọ́run
33 (A)A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!
Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,
ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 (B)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?
Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 (C)“Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,
tí a kò sì san padà fún un?”
36 (D)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.
Ẹbọ ààyè mímọ́
12 (E)Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2 (F)Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.
Òwe tálẹ́ǹtì
14 (A)“A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn. 15 Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀. 16 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn. 17 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn. 18 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.
19 (B)“Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn ṣírò owó rẹ̀. 20 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’
21 (C)“Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’
22 “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’
23 “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’
24 “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí. 25 Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’
26 “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí. 27 Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.
28 “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. 29 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. 30 Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.