Book of Common Prayer
Kíkígbe fún ìgbàlà
145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
dá mi lóhùn Olúwa,
èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
Pípa òfin mọ́ ni ìpọ́njú
153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
Orin fún ìgòkè.
Ìbẹ̀rù Olúwa dára
128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5 Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.
Orin fún ìgòkè.
129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá”
ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá;
síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
4 Olódodo ni Olúwa:
ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
7 Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Orin fún ìgòkè.
130 Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 (A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli
12 Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín. 2 Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí. 3 Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni ààmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”
4 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
5 Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni ààmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”
Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti.
16 “Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! 17 Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”
18 Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.
19 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”
20 Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa. 21 Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n. 22 Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀. 23 Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́. 24 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín; Ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. 25 Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”
14 Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. 15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: 16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. 17 Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.
18 Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! 21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. 22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23 (A)Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”
24 Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìhìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.
23 (A)Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu. 2 (B)Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”
3 (C)Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”
Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”
4 (D)Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”
5 Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”
6 Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili. 7 Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.
8 (E)Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ ààmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. 9 (F)Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá. 10 Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi. 11 (G)Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ. 12 Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà: nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.