Book of Common Prayer
Orin fún ìgòkè.
120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
ó sì dá mi lóhùn
2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3 Kí ni kí a fi fún ọ?
Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kedari!
6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.
Orin fún ìgòkè.
121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá
Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
yóò pa ọkàn rẹ mọ́
8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
ìwọ Jerusalẹmu.
3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
Orin fún ìgòkè.
123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
2 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
3 Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
4 Nígbà náà ni omi
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
5 Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
okùn já àwa sì yọ.
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Orin fún ìgòkè.
125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
4 Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.
Orin fún ìgòkè.
126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,
bí ìṣàn omi ní gúúsù.
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
yóò fi ayọ̀ ka.
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
yóò sì ru ìtí rẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
ojú kì yóò tì wọ́n,
ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
Saulu gba ìlú Jabesi sílẹ̀
11 Nahaṣi ará Ammoni gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi Gileadi, gbogbo ọkùnrin Jabesi sì wí fún Nahaṣi pé, “Bá wa dá májẹ̀mú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”
2 Ṣùgbọ́n Nahaṣi ará Ammoni sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi yóò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò, èmi yóò ṣì fi yín ṣe ẹlẹ́yà lójú gbogbo Israẹli.”
3 Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”
4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún. 5 Nígbà náà gan an ni Saulu padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sọkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi.
6 Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè. 7 Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo. 8 Nígbà tí Saulu sì kó wọn jọ ní Beseki, àwọn ọkùnrin Israẹli tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. (300,000) àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000).
9 Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jabesi, inú wọn sì dùn. 10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Jabesi pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”
11 Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.
Wọ́n fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba
12 Àwọn ènìyàn sọ fún Samuẹli pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Saulu yóò ha jẹ ọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”
13 Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.”
14 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.” 15 Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.
8 (A)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká
Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. 2 Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Filipi ní Samaria
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5 Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. 8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
Simoni onídán
9 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun. 10 Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.” 11 Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn. 13 Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ n gan Jesu
63 (A)Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
Jesu níwájú Pilatu àti Herodu
66 (B)Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67 (C)“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”
Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́; 68 Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). 69 Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”
70 (D)Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”
71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.