Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:1-24

119 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
    ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
    tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
    wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
    kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
    láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
    nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
    bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀:
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
    má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
    kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12 Ìyìn ni fún Olúwa;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
    gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
    bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
    èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
    èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.

Ohun ìyanu tí o wà nínú òfin rẹ̀

17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
    èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
    ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
    Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
    nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
    tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
    nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
    ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
    àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.

Saamu 12-14

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
    Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
    ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

Olúwa kí ó gé ètè èké wọn
    àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
tí ó wí pé,
    “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
    àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”

“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
    Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.
    “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,
    gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
    tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́
    kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
    nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
    Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
    àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
    Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?

Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
    Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
    àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
    ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
    nítorí ó dára sí mi.

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

14 (A)(B) Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
    “Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
    kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
    lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
    ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
    kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
    kò sí ẹnìkan.

Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
    wọn kò sì ké pe Olúwa?
Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
    nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
    ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
    Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
    jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

1 Samuẹli 16:1-13

Samuẹli fi òróró yan Dafidi

16 Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Saulu, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jese ará Bẹtilẹhẹmu. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”

Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.”

Olúwa wí pé, “Mú abo ẹgbọrọ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa.’ Pe Jese wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fihàn ọ́.”

Samuẹli ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”

Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

Nígbà náà ni Jese pe Abinadabu, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Samuẹli. Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.” Jese sì jẹ́ kí Ṣamma rìn kọjá ní iwájú Samuẹli, ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.” 10 Jese jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Samuẹli ṣùgbọ́n Samuẹli sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.” 11 Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”

Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”

Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

12 Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.

Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.”

13 Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí mímọ́ Olúwa wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.

Ìṣe àwọn Aposteli 10:1-16

Àwọn ìpè Korneliu fún Peteru

10 (A)Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”

Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”

Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.

Ìran Peteru

Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́: 10 Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran. 11 Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀: 12 Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 13 Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”

14 Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”

15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

16 Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

Luku 24:12-35

12 Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

Ní ojú ọnà sí Emmausi

13 Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. 14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 16 (A)Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”

Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

19 (B)Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, 20 Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. 21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. 22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: 23 Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. 24 (C)Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”

25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: 26 Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” 27 (D)Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

28 (E)Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. 29 Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.

30 (F)Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. 31 Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú 32 Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”

33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, 34 (G)Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.