Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa
36 (A)Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé;
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
níwájú wọn.
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3 Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4 “Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5 Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
Saulu gbìyànjú láti pa Dafidi
19 Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀ 2 Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sápamọ́ sí ibẹ̀. 3 Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”
4 Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀. 5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?”
6 Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”
7 Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀.
8 Lẹ́ẹ̀kan an sí i ogun tún wá, Dafidi sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Filistini jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.
9 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, 10 Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.
11 Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.” 12 Nígbà náà Mikali sì gbé Dafidi sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó. 13 Mikali gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.
14 Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”
15 Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.” 16 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.
17 Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?”
Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’ ”
18 Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀.
Peteru bọ́ kúrò ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìyanu
12 Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. 2 Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. 3 Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. 4 Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.
5 Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.
6 Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. 7 Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.
8 Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” 9 Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. 10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
11 Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!”
12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”
16 Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17 Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.
Jesu wo aláàrùn ẹ̀gbà sàn
2 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé. 2 Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn. 3 (A)Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. 4 Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. 5 Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, 7 “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
8 Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 9 Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’ 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, 11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.” 12 (B)Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.