Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 19:7-14

Pípé ni òfin Olúwa,
    ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
    ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
    òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
    ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
    àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
    Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
    má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
    èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Deuteronomi 1:1-18

Àṣẹ láti jáde kúrò ní Horebu

Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah: ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu. (Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)

Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.

Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé:

Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó. Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate. Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

Yíyan àwọn olórí

(A)Mo wí fún un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé. 10 Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run. 11 Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. 12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín? 13 Ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

14 Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbèrò láti ṣe nì dára.”

15 Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín: olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín. 16 (B)Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò. 17 Ẹ má sì ṣe ojúsàájú ní ìdájọ́: Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ. 18 Nígbà náà ni èmi yóò sọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.

Ìṣe àwọn Aposteli 12:20-25

20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ.

21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.

24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.

25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.