Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 106:1-6

106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
    Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
    ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
    Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Rántí mi, Olúwa,
    Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
    wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
    kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
    ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
    àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
    a sì ti hùwà búburú

Saamu 106:13-23

13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
    wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
    nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
    ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
    pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
    ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
    iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
    wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
    sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
    ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
    àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
    bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
    tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

Saamu 106:47-48

47 (A)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
    kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
    láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

Deuteronomi 4:15-20

Èèwọ̀ ni ìbọ̀rìṣà jẹ́

15 Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi, 16 kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, 17 tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú, 18 tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi. 19 Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run. 20 Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ejibiti, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

1 Peteru 2:19-25

19 Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run. 20 Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 21 Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀:

22 (A)“Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan,
    bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.”

23 Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́. 24 (B)Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá. 25 Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùṣọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.