Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 106:1-6

106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
    Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
    ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
    Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Rántí mi, Olúwa,
    Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
    wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
    kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
    ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
    àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
    a sì ti hùwà búburú

Saamu 106:13-23

13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
    wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
    nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
    ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
    pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
    ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
    iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
    wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
    sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
    ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
    àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
    bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
    tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

Saamu 106:47-48

47 (A)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
    kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
    láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

Deuteronomi 4:21-40

21 Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jordani kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín. 22 Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jordani kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdìkejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà. 23 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá: Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí. 24 Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

25 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́: Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú. 26 Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jordani kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátápátá. 27 Olúwa yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú yín ni yóò yè láàrín orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò fọ́n yín sí. 28 Ẹ ó sì máa sin ọlọ́run tí á fi ọwọ́ ènìyàn ṣe: tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn. 29 Bí ẹ̀yin bá wá Olúwa Ọlọ́run yín láti bẹ̀ ẹ́, ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín. 30 Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀. 31 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.

Olúwa ni Ọlọ́run

32 Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí? 33 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè? 34 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnrarẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ ààmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?

35 A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. 36 Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá, 37 torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti. 38 Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.

39 Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́. 40 Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.

Marku 7:9-23

Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. 10 (A)Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. 13 Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

14 Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. 15 Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. 16 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

17 (B)Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. 18 (C)Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? 19 Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)

20 (D)Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. 21 Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, 22 (E)ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23 Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.