Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:169-176

169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
    fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
    nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
    nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
    nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
    kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
    sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

1 Ọba 13:1-10

Ènìyàn Ọlọ́run kan láti Juda

13 Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní ààmì kan wí pé: “Èyí ni ààmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”

Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ààmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ” 10 Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.

Romu 3:9-20

Kò sí olóòtítọ́ kan

(A)Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 10 (B)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan
11     Kò sí ẹni tí òye yé,
    kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
12 Gbogbo wọn ni ó ti yapa,
    wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;
kò sí ẹni tí ń ṣe rere,
    kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
13 (C)“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:
    ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”
“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”
14     (D)“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”
15 (E)“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:
16     ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.
17 Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”
18     (F)“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

19 (G)Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 20 (H)Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.