Revised Common Lectionary (Complementary)
7 Pípé ni òfin Olúwa,
ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8 Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
9 Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
òdodo ni gbogbo wọn.
10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.
13 Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 14 Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”
15 Mose dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. 16 Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrín ẹnìkínní àti ẹnìkejì, èmi a sì máa mú wọn mọ òfin àti ìlànà Ọlọ́run.”
17 Àna Mose dá a lóhùn pé, “Ohun tí o ń ṣe yìí kò dára. 18 Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe 19 Nísinsin yìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè-àìyedè wá sí iwájú rẹ̀. 20 Kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà-bí-Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe. 21 Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá. 22 Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe. 23 Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni àlàáfíà.”
24 Mose fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un. 25 Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá. 26 Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mose wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fúnrawọn.
27 Mose sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jetro sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
13 Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé. 14 Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò. 16 Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ ààmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí. 17 Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”
18 Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu. 19 Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò. 20 Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.”
21 Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe. 22 Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ ààmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.
Àdúrà àwọn onígbàgbọ́
23 Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. 24 (A)Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 25 (B)Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé:
“ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú,
àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán?
26 Àwọn ọba ayé dìde,
àti àwọn ìjòyè kó ara wọn
jọ sí Olúwa,
àti sí ẹni ààmì òróró rẹ̀.’
27 (C)Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi ààmì òróró yàn, 28 Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe. 29 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ. 30 Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”
31 Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.