Revised Common Lectionary (Complementary)
ÌWÉ KARÙN-ÚN
Saamu 107–150
107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá.
23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀
ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí
37 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńláńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
wọn a sì wà ni ipò wọn.
9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
ibú omi á sì súnkì.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
25 (A)(B) “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27 (C)Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.