Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 52

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
    Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
    ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
    ó dàbí abẹ mímú,
    ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
    àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
    yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
    yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
    wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
    bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
    ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
    tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
    láé àti láéláé.
Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
    èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
    Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Jeremiah 22:1-9

Ìdájọ́ fún àwọn ọba búburú

22 Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí. Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí. Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,
    gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,
dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,
    àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.
Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,
    olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,
wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,
    wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’ Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”

Luku 6:43-45

Igi àti èso rẹ̀

43 (A)“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. 44 Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. 45 (B)Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.