Revised Common Lectionary (Complementary)
ÌWÉ KARÙN-ÚN
Saamu 107–150
107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá.
23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀
ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
21 “Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí,
wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.
22 Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́;
ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.
23 Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò;
wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.
24 Èmi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́;
ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye sí wọn.
25 Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn;
Mo jókòó bí ọba ní àárín ológun rẹ̀;
Mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.
Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ Jobu
30 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,
àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà
baba ẹni tí èmi kẹ́gàn
láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
2 Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,
níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
3 Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn
wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ
ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.
4 Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó;
gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.
5 A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn,
àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6 A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta Àfonífojì,
nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7 Wọ́n ń dún ní àárín igbó
wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
8 Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,
àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;
àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
10 Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,
wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
11 Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;
àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
12 Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;
wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò,
wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
13 Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú;
wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀,
àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
14 Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru;
ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
15 Ẹ̀rù ńlá bà mí;
wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù,
àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
Sí Jerusalẹmu
21 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, àti gba ibẹ̀ lọ sí Patara: 2 A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. 3 Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. 4 Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. 5 Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. 6 Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.
7 Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. 8 Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.
10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”
12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13 Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”
15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.