Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 92:1-4

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Saamu 92:12-15

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

1 Ọba 10:26-11:8

26 Solomoni sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní egbèje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàata (13,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú ọba ní Jerusalẹmu. 27 Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní Àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. 28 A mú àwọn ẹṣin wá fún Solomoni láti Ejibiti àti láti Kue, oníṣòwò ọba rà wọ́n láti Kue fún owó. 29 Wọ́n ń mú kẹ̀kẹ́ kan gòkè láti Ejibiti wá fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún àádọ́jọ (150). Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mú wọn wá fún ọba àwọn ọmọ Hiti àti ọba àwọn ọmọ Aramu.

Àwọn ìyàwó Solomoni

11 Solomoni ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Farao, àwọn ọmọbìnrin Moabu, àti ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni àti ti àwọn ọmọ Hiti. Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn.

Heberu 11:4-7

(A)Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.

(B)Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Enoku ní ipò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sì rí i mọ́, nítorí Ọlọ́run ṣí i ní ipò padà: nítorí ṣáájú ìṣípò padà rẹ̀, a jẹ́rìí yìí sí i pé o wu Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

(C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tí ì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.