Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.
46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.
4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
7 Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
8 Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
A ó gbé mi ga ní ayé.
11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
18 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’
Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’
19 A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè
Jerusalẹmu.”
20 “Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta
kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani,
kí o kígbe sókè láti Abarimu,
nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.
21 Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,
ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’
Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,
ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.
22 Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,
gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn,
nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́
nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
23 Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’
tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari,
ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,
ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!
24 “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀. 25 Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli. 26 Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí. 27 Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”
28 Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,
ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?
Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè
sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.
29 Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,
gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
30 Báyìí ni Olúwa wí:
“Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,
ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀;
nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere,
èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi
tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”
Àwọn ọmọdé àti Jesu
15 (A)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.