Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 32:1-7

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Jobu 22:21-23:17

21 “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
    nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
22 Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
    kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
23 Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró:
    Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
24 Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀
    lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò,
25 Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
    àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
26 Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
    ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
27 Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
    ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
    ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
29 Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
    nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’
    Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
30 Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,
    a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Èsì Jobu

23 Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé:

“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
    ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
    Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
    ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá
    mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
    Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
    níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,
    òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,
    ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10 Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,
    nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11 Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;
    ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,
    èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.

13 “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
    Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14 Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
    nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16 Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
    Olódùmarè sì ń dààmú mi.
17 Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

2 Peteru 1:1-11

Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi,

Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà.

Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.

Mímú kí ìpè àti yíyàn ẹni dájú

Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.

10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.