Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 123

Orin fún ìgòkè.

123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
Kíyèsi, bí ojú àwọn
    ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
    àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
    títí yóò fi ṣàánú fún wa.

Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
    nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
Ọkàn wa kún púpọ̀
    fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
    àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Jobu 25-26

Ìdáhùn Bilidadi

25 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé:

“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,
    òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,
    tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
    Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,
    àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,
    àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

Ìdáhùn Jobu

26 Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé:

Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
    báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
    tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
    àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
    lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
    ibi ìparun kò sí ní ibojì.
Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
    ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
    àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
    ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10 Ó fi ìdè yí omi Òkun ká,
    títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11 Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
    ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
    nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
    ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
14 Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
    ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
    Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

Johanu 5:19-29

19 (A)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (B)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (C)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (D)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

24 (E)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. 25 (F)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.

28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (G)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.