Revised Common Lectionary (Complementary)
Ọjọ́ Olúwa n bọ
4 “Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn. 2 Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7 Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
Ìkìlọ̀ ní ṣíṣe ìmẹ́lẹ́
6 (A)Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. 7 (B)Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. 8 (C)Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. 9 (D)Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. 10 (E)Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”
11 (F)A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri. 12 (G)Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. 13 (H)Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.
Àwọn ààmì ìkẹyìn ayé
5 (A)Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé 6 (B)“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
7 (C)Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”
8 (D)Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. 9 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”
10 (E)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. 11 Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.
12 (F)(G) “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. 13 (H)Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. 14 (I)Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. 16 (J)A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. 17 (K)A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 18 (L)Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. 19 (M)Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.