Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu ti Dafidi.
141 Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:
kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
5 Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́:
jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.
Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú
6 A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,
àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
7 Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”
8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;
nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,
kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,
nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
Ògo padà sí inú ilé Ọlọ́run
43 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, 2 (A)mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀. 3 Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀. 4 Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá. 5 Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.
6 Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run. 7 Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga. 8 Nígbà tí wọ́n ba gbé ìloro ilé wọn kángun sí ìloro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárín èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi. 9 Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé.
10 “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, 11 tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.
12 “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà.
37 (A)“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀. 38 Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. 39 Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”
Àwọn ààmì òpin ayé
24 (B)Bí Jesu ti ń kúrò ni tẹmpili, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n fẹ́ fi ẹwà tẹmpili náà hàn án. 2 (C)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
3 (D)Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ ààmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?”
4 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. 5 Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kristi náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. 6 Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà. 7 Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀. 8 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.
9 (E)“Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. 10 Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, 11 ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. 12 Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, 13 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. 14 A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.