Revised Common Lectionary (Complementary)
8 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
9 Wo asà wa, Ọlọ́run;
fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.
10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Àdúrà Hana
2 Hana sì gbàdúrà pé:
“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;
Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.
Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,
nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.
2 “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;
kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;
kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
3 “Má ṣe halẹ̀;
má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde
nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,
láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.
4 “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,
àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
5 Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,
àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.
Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.
Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.
6 “Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.
7 Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;
ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
8 Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,
ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,
láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,
láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo:
“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,
ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
9 Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.
“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10 A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.
“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.”
Jíjìyà fun jíjẹ́ onígbàgbọ́
12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: 13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 14 (A)Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?
18 (B)“Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,
níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò yọjú sí?”
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtítọ́ lọ́wọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.