Revised Common Lectionary (Complementary)
Ìwòsàn Naamani adẹ́tẹ̀
5 Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.
2 Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. 3 Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
7 Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”
8 Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” 9 Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. 10 Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”
11 Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. 12 Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.
13 Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” 14 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.
15 Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”
111 Ẹ máa yin Olúwa.
Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
2 Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
8 Wọ́n dúró láé àti láé,
ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.
10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
ìyìn rẹ̀ dúró láé.
8 Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. 9 Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.
11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:
Bi àwa bá bá a kú,
àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,
àwa ó sì bá a jẹ ọba:
Bí àwa bá sẹ́ ẹ,
òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,
òun dúró ni olóòtítọ́:
Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.
Òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn
14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ
Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá
11 (A)Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12 (B)Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: 13 (C)Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”
14 (D)Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.
17 Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19 (E)Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.