Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Habakuku 1:1-4

Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.

Ìráhùn Habakuku

(A)Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
    Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
    ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé
    Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
    ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
    ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
    Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.

Habakuku 2:1-4

Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku

(A)Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye
    Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre
Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
    àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

Ìdáhùn Olúwa

Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé:

“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
    kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
    kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
(B)Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
    yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
    kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
    nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

(C)“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga;
    Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
    ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Saamu 37:1-9

Ti Dafidi.

37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
    kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
    wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.

Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
    òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
    gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
    àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
    kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
    nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.

Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
    má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
    ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

2 Timotiu 1:1-14

Ọ̀rọ̀ ìkíni

Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.

Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:

Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti jẹ́ onígbàgbọ́

Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀. (A)Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.

Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere nípa agbára Ọlọ́run, ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, 10 ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìhìnrere. 11 Fún ti ìhìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. 12 Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

Luku 17:5-10

(A)(B) Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”

Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.

“Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’? (C)Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’? Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. 10 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.