Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 61

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

2 Ọba 5:15-19

15 Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

16 Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò nígbà ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naamani rọ̀ ọ́ láti gbà á, ó kọ̀.

17 Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí Olúwa. 18 Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí Olúwa dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19 Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.”

Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà,

Ìṣe àwọn Aposteli 26:24-29

24 Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

25 Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde. 26 Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀. 27 Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

28 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

29 Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.