Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè.
3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6 Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà
14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:
2 “Juda káàánú,
àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
3 Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
wọ́n sì bo orí wọn.
4 Ilẹ̀ náà sán
nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
wọ́n sì bo orí wọn.
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
torí pé kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”
Orin Maria
46 Maria sì dáhùn, ó ní:
“Ọkàn mi yin Olúwa lógo,
47 Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48 Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó.
Láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀
láti ìrandíran.
51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54 Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55 (A)sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.