Old/New Testament
Natani bá Dafidi wí
12 Olúwa sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. 2 Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀. 3 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.
4 “Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀: láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá: o sì mú àgùntàn ọkùnrin tálákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”
5 Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. 6 Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”
7 Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu. 8 Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. 9 Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’
11 “Báyìí ni Olúwa wí, Kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. 12 Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ”
13 Dafidi sì wí fún Natani pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”
Natani sì wí fún Dafidi pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú. 14 Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀-òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”
Ọmọ náà kú
15 Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀. 16 Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà. 17 Àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.
18 Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”
19 Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú: Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”
20 Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’ 23 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
Batṣeba sì tún bí ọmọ mìíràn tí a pè ní Solomoni
24 Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni: Olúwa sì fẹ́ ẹ. 25 Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa.
Ìṣẹ́gun Dafidi lórí àwọn Ammoni
26 (A)Joabu sì bá Rabba ti àwọn ọmọ Ammoni jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn. 27 Joabu sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rabba jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olómi. 28 Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má bá à gba ìlú náà kí a má ba à pè é ní orúkọ mi.”
29 Dafidi sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rabba, ó sì bá a jà, ó sì gbà á. 30 Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ tálẹ́ǹtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dafidi lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀. 31 Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtulẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Dafidi àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jerusalẹmu.
Amnoni àti Tamari
13 Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.
2 Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.
3 Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi: Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. 4 Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”
Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”
5 Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”
6 Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”
7 Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” 8 Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. 9 Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.
Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. 11 Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”
12 Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 13 Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” 14 Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.
15 Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”
16 Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.”
Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. 17 Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18 Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. 19 Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.
Absalomu kọlu Amnoni
20 Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi. 22 Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.
23 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24 Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”
25 Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.
26 Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”
Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” 27 Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
28 Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” 29 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.
30 Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31 Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.
32 Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 33 Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.”
Absalomu sálọ sí Geṣuri
34 Absalomu sì sá.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”
35 Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”
36 Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.
37 Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.
38 Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. 39 Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.
Òwe ọlọ́gbọ́n òṣìṣẹ́
16 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. 2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’
3 “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. 4 Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’
5 “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’
6 “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n òróró.’
“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’
7 “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’
“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n alikama.’
“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’
8 (A)“Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. 9 (B)Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.
10 (C)“Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú. 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín? 12 Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín?
13 (D)“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.”
14 Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i. 15 (E)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dá àre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín: nítorí ohun ti a gbéga lójú ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run.
Àfikún àwọn ẹ̀kọ́
16 (F)“Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀. 17 (G)Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí èyí tí ó kéré jù nínú òfin kí ó yẹ.
18 (H)“Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé ẹlòmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀sílẹ̀ ní ìyàwó náà, ó ṣe panṣágà.
Ọlọ́rọ̀ kan àti Lasaru
19 “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́: 20 (I)Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, 21 Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.
22 (J)“Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; 23 Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀. 24 Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’
25 (K)“Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró. 26 Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’
27 “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi: 28 Nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’
29 (L)“Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’
30 (M)“Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’
31 “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.