Old/New Testament
Samuẹli fi Saulu bú
13 Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì.
2 Saulu yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.
3 Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” 4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali.
5 Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́dógún kẹ̀kẹ́, (3,000) ẹgbẹ̀ta (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. 6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. 7 Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.
Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. 8 Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. 9 Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. 10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i.
11 Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”
Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, 12 mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”
13 Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. 14 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”
15 Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.
Israẹli láìní ohun ìjà
16 Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gibeah ti Benjamini, nígbà tí àwọn Filistini dó ní Mikmasi. 17 Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, 18 òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí Àfonífojì Ṣeboimu tí ó kọjú sí ijù.
19 A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” 20 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. 21 Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.
Jonatani kọlu àwọn ará Filistini
22 Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n.
23 Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi. 14 1 Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.
2 Saulu sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gibeah lábẹ́ igi pomegiranate èyí tí ó wà ní Migroni. Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin (600) sì wà pẹ̀lú rẹ̀, 3 lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà Olúwa ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ.
4 Ní ọ̀nà tí Jonatani ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Filistini, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkínní sì ń jẹ́ Bosesi, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sene. 5 Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah.
6 Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.”
7 Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”
8 Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. 9 Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. 10 Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”
11 Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” 12 Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”
Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.”
13 Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 14 Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀.
15 Nígbà náà ni ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ọmọ-ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
Àwọn ogun Filistini sá àsálà
16 Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Saulu ní Gibeah ti Benjamini sì rí àwọn ọmọ-ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà. 17 Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wò ó, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.
18 Saulu sì wí fún Ahijah pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbà náà. 19 Nígbà tí Saulu sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Filistini sì ń pọ̀ síwájú sí. Saulu sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”
20 Saulu àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Filistini ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkejì rẹ̀. 21 Àwọn Heberu tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Filistini tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani. 22 Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná. 23 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni.
Jonatani jẹ oyin
24 Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.
25 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà. 26 Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ síbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré. 27 Ṣùgbọ́n Jonatani kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán. 28 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”
29 Jonatani sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdààmú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí. 30 Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀tá wọn lónìí, pípa àwọn Filistini ìbá ti pọ̀ tó?”
31 Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà. 32 Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀. 33 Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.”
Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.” 34 Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ”
Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀. 35 Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.
36 Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.”
Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.”
Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”
37 Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.
38 Saulu sì wí pé, “Ẹ wá síhìn-ín ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí. 39 Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.
40 Nígbà náà ni Saulu wí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jonatani ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.”
Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”
41 Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege. 42 Saulu sì wí pé, “Ẹ dìbò láàrín èmi àti Jonatani ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jonatani.
43 Saulu sì wí fún Jonatani pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”
Jonatani sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsin yìí ṣé mo ní láti kú?”
44 Saulu sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, nítorí pé ìwọ Jonatani yóò sá à kú dandan.”
45 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Saulu pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jonatani kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Israẹli? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jonatani sílẹ̀, kò sì kú.
46 Nígbà náà ni Saulu sì dẹ́kun lílépa àwọn Filistini, àwọn Filistini sì padà sí ìlú wọn.
47 Lẹ́yìn ìgbà tí Saulu ti jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni; Edomu, àti àwọn ọba Ṣoba, àti àwọn Filistini. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n. 48 Ó sì jà tagbára tagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Amaleki, ó sì ń gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n.
Ìdílé Saulu
49 (A)Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali. 50 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Ahinoamu ọmọbìnrin Ahimasi. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arákùnrin baba Saulu. 51 Kiṣi baba Saulu àti Neri baba Abneri wọ́n sì jẹ́ ọmọ Abieli.
52 Ní gbogbo ọjọ́ Saulu, ogun náà sì gbóná sí àwọn Filistini, níbikíbi tí Saulu bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.
Jesu rán àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde
10 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. 2 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. 3 (C)Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. 4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.
5 (D)“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ 6 Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. 7 (E)Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.
8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: 9 Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10 Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 11 (F)‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ 12 (G)Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.
13 (H)“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. 14 Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15 Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.
16 (I)“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 20 (K)Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”
21 (L)(M) Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.
22 (N)“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”
23 (O)Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24 Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.