Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 3-5

Abneri àti Iṣboṣeti jà

Ogun náà sì pẹ́ títí láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi: agbára Dafidi sì ń pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n ìdílé Saulu ń rẹ̀yìn sí i.

(A)Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni:

Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un.

Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un;

ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.

Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;

àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali;

Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un.

Wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni.

Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi, Abneri sì dì alágbára ní ìdílé Saulu. Saulu ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah: Iṣboṣeti sì bi Abneri léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”

Abneri sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣboṣeti sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Juda bí? Di òní yìí ni mo ṣàánú fún ìdílé Saulu baba rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dafidi lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Abneri, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dafidi, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un. 10 Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.” 11 Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.”

13 Òun sì wí pé, “Ó dára, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Mikali ọmọbìnrin Saulu wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.” 14 Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Iṣboṣeti ọmọ Saulu pé, “Fi Mikali obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́ọ̀rún awọ iwájú orí àwọn Filistini fẹ́.”

15 Iṣboṣeti sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Paltieli ọmọ Laiṣi. 16 Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sọkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Bahurimu Abneri sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.

Abneri wá kí Dafidi ní Hebroni

17 Abneri sì bá àwọn àgbàgbà Israẹli sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dafidi ní ìgbà àtijọ́, láti jẹ ọba lórí yín. 18 Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi pé, ‘Láti ọwọ́ Dafidi ìránṣẹ́ mi lé mi ó gba Israẹli ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn.’ ”

19 Abneri sì sọ̀rọ̀ létí Benjamini: Abneri sì lọ sọ létí Dafidi ní Hebroni, gbogbo èyí tí ó dára lójú Israẹli, àti lójú gbogbo ilé Benjamini. 20 Abneri sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dafidi sì ṣe àsè fún Abneri àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. 21 Abneri sì wí fún Dafidi pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Israẹli jọ sọ́dọ̀ ọba olúwa mi, wọn ó sì bá a ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jẹ ọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dafidi sì rán Abneri lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.

Joabu gbọ́ nípa wíwá Abneri sí Hebroni

22 Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ: òun sì ti lọ ní Àlàáfíà. 23 Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.

24 Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ. 25 Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”

Joabu pa Abneri

26 Nígbà tí Joabu sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Abneri, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sira: Dafidi kò sì mọ̀. 27 Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀.

28 Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Abneri ọmọ Neri: 29 Jẹ́ kí ó wà ní orí Joabu, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní ààrùn ìsun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi idà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Joabu.”

30 (Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.)

31 Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀. 32 Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún.

33 Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé:

“Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?
34     A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà.
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.”

Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.

35 Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!”

36 Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn: gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà. 37 Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri.

38 Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli. 39 Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jẹ ọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Seruiah sì le jù mí lọ: Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”

Ikú Iṣboṣeti

Nígbà tí ọmọ Saulu sì gbọ́ pé, Abneri kú ní Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Israẹli sì rẹ̀wẹ̀sì. Ọmọ Saulu sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Baanah, àti orúkọ èkejì ní Rekabu, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti ti àwọn ọmọ Benjamini (nítorí pé a sì ka Beeroti pẹ̀lú Benjamini). Àwọn ará Beeroti sì ti sálọ sí Gittaimu, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

(Jonatani ọmọ Saulu sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìròyìn dé ní ti Saulu àti Jonatani láti Jesreeli wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sálọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sálọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mefiboṣeti.)

Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí. Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ).

Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”

Dafidi sì dá Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú. 10 Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Saulu ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Siklagi, ẹni tí ó ṣe bí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìròyìn rere rẹ̀. 11 Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìkà ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láààyè.”

12 Dafidi sì fi àṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hebroni. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Iṣboṣeti, wọ́n sì sin ín ní ibojì Abneri ní Hebroni.

A fi Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli

(B)Gbogbo ẹ̀yà Israẹli sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa ń í ṣe. Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Saulu fi jẹ ọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Israẹli jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò ṣe olùṣọ́ Israẹli àwọn ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún Israẹli.’ ”

Gbogbo àgbàgbà Israẹli sì tọ ọba wá ní Hebroni, Dafidi ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hebroni, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba Israẹli.

(C)Dafidi sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba; ó sì jẹ ọba ní ogójì ọdún. Ó jẹ ọba ní Hebroni ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Juda: ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Israẹli àti Juda.

Dafidi fi agbára gba Jerusalẹmu

(D)Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn ará Jebusi, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dafidi pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dafidi kì yóò lè wá síhìn-ín.” Ṣùgbọ́n Dafidi fi agbára gba ìlú odi Sioni: èyí náà ni í ṣe ìlú Dafidi.

Dafidi sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jebusi, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dafidi kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

Dafidi sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ-ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dafidi. Dafidi mọ ògiri yí i ká láti Millo wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀. 10 Dafidi sì ń pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

11 (E)Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi. 12 Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀.

13 Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi. 14 (F)Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. 15 Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. 16 Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti.

Dafidi ṣẹ́gun àwọn Filistini

17 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi. 18 Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní Àfonífojì Refaimu. 19 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?”

Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.”

20 Dafidi sì dé Baali-Perasimu, Dafidi sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọ̀tá mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baali-Perasimu. 21 Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.

22 (G)Àwọn Filistini sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní Àfonífojì Refaimu. 23 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Baka. 24 Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi Baka náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Filistini.” 25 Dafidi sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un; ó sì kọlu àwọn Filistini láti Geba títí dé Geseri.

Luku 14:25-35

Àmúyẹ láti jẹ ọmọ-ẹ̀yìn

25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, 26 (A)“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 27 (B)Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

28 “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29 Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30 Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’

31 “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàárùn-ún pàdé ẹni tí ń mú ẹgbàáwàá bọ̀ wá ko òun lójú? 32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà. 33 (C)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

34 (D)“Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn? 35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.

“Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.