Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 22-24

Dafidi ní Adullamu àti Mispa

22 Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin.

Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà.

Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti.

Saulu pa àwọn àlùfáà Nobu

Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10 Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

11 Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. 12 Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.”

Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”

13 Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

14 Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. 15 Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.”

16 Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”

17 Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.”

Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

18 Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin (85) ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. 19 Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

20 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ. 21 Abiatari sì fihan Dafidi pé Saulu pa àwọn àlùfáà Olúwa tán. 22 Dafidi sì wí fún Abiatari pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Doegi ará Edomu ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Saulu: nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ. 23 Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”

Dafidi gbà Keila lọ́wọ́ àwọn Filistini

23 Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?”

Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”

Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?”

Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Keila, wọ́n sì bá àwọn ará Filistini jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dafidi sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀. Ó sì ṣe, nígbà tí Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú efodu kan lọ́wọ́ rẹ̀.

A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.” Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín-yìí!” 10 Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. 11 Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?”

Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

12 Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?”

Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

13 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.”

14 Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sápamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

Àwọn ará Sifi dalẹ̀ Dafidi

15 Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. 16 Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. 17 Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” 18 Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀.

19 Àwọn ará Sifi sì gòkè tọ Saulu wá sí Gibeah, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ́ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Horeṣi, ní òkè Hakila, tí ó wà níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 20 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.”

21 Saulu sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi. 22 Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ. 23 Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!”

24 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi: ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 25 Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dafidi: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní aginjù ti Maoni. Saulu sì gbọ́, ó sì lépa Dafidi ní aginjù Maoni.

26 Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn. 27 Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Saulu wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Filistini ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.” 28 Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”). 29 Dafidi sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní En-Gedi.

Dafidi da ẹ̀mí Saulu sí

24 Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” Saulu sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.

Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu.

Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni.” Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? 10 Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’ 11 Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. 12 Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 13 Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

14 “Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15 Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

16 Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17 Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18 Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí. 19 Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí. 20 Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Israẹli yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ. 21 Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

22 Dafidi sì búra fún Saulu. Saulu sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.

Luku 12:1-31

Àwọn ìkìlọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìyànjú

12 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè. (B)Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.

(C)(D) “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́. (E)Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù. Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? (F)Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.

“Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run: (G)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run. 10 (H)Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.

11 (I)“Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí: 12 Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”

Ìtàn òmùgọ̀ ọlọ́rọ̀

13 Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”

14 Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?” 15 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”

16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’

18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

20 (K)“Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

Má ṣe ṣe àníyàn

22 (L) Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. 23 Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. 24 (M)Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! 25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?

27 (N)“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. 30 (O)Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. 31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.