Old/New Testament
Ìpín fún ẹ̀yà Efraimu àti Manase
16 Ìpín ti àwọn ọmọ Josẹfu láti Jordani lẹ́bàá Jeriko, ní omi Jeriko ní ìhà ìlà-oòrùn, àní aginjù, tí ó gòkè láti Jeriko lọ dé ilẹ̀ òkè Beteli. 2 Ó sì tẹ̀síwájú láti Beteli (tí í ṣe Lusi) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Arki ní Atarotu, 3 Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jefileti, títí dé ilẹ̀ ìsàlẹ̀ Beti-Horoni, àní dé Geseri, ó sì parí sí etí Òkun.
4 Báyìí ni Manase àti Efraimu, àwọn ọmọ Josẹfu, gba ilẹ̀ ìní wọn.
5 Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé:
Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí Òkè Beti-Horoni. 6 Ó sì lọ títí dé Òkun. Láti Mikmeta ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Ṣilo, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Janoa ní ìlà-oòrùn. 7 Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani. 8 Láti Tapua ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Rafini, ó sì parí ní Òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.
9 Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.
10 (A)Wọn kò lé àwọn ara Kenaani tí ń gbé ni Geseri kúrò, títí di òní yìí ni àwọn ará Kenaani ń gbé láàrín àwọn ènìyàn Efraimu, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.
17 Èyí ní ìpín ẹ̀yà Manase tí í ṣe àkọ́bí Josẹfu, fún Makiri, àkọ́bí Manase. Makiri sì ni baba ńlá àwọn ọmọ Gileadi, tí ó ti gba Gileadi àti Baṣani nítorí pé àwọn ọmọ Makiri jẹ́ jagunjagun ńlá. 2 Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Manase: ní agbo ilé Abieseri, Heleki, Asrieli, Ṣekemu, Heferi àti Ṣemida. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Manase ọmọ Josẹfu ní agbo ilé wọn.
3 (B)Nísinsin yìí Ṣelofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa. 4 Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. 5 Ìpín ilẹ̀ Manase sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gileadi àti Baṣani ìlà-oòrùn Jordani, 6 Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Manase gba ìní ní àárín àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gileadi sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Manase.
7 Agbègbè Manase sì fẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikmeta ní ìlà-oòrùn Ṣekemu. Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tapua, 8 (Manase lo ni ilẹ̀ Tapua, ṣùgbọ́n Tapua fúnrarẹ̀ to wà ni ààlà ilẹ̀ Manase jẹ ti àwọn ará Efraimu.) 9 Ààlà rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ odò Kana, ní ìhà gúúsù odò náà. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Efraimu wà ní àárín àwọn ìlú Manase, ṣùgbọ́n ààlà Manase ni ìhà àríwá odò náà, ó sì yọ sí Òkun. 10 Ìhà gúúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Efraimu, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Manase. Ilẹ̀ Manase dé Òkun, Aṣeri sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà tí Isakari jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn.
11 (C)Ní àárín Isakari àti Aṣeri, Manase tún ni Beti-Ṣeani, Ibleamu àti àwọn ènìyàn Dori, Endori, Taanaki àti Megido pẹ̀lú àwọn abúlé tí ó yí wọn ká (ẹ̀kẹ́ta nínú orúkọ wọn ní Nafoti).
12 Síbẹ̀, àwọn ọmọ Manase kò lè gba àwọn ìlú wọ̀nyí, nítorí àwọn ará Kenaani ti pinnu láti gbé ní ilẹ̀ náà. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kenaani sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátápátá.
14 Àwọn ọmọ Josẹfu sì wí fún Joṣua pé, “Èéṣe tí ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdákan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀.”
15 Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Efraimu bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì ṣán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Peresi àti ará Refaimu.”
16 Àwọn ènìyàn Josẹfu dáhùn pé, “Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kenaani tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Beti-Ṣeani àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní Àfonífojì Jesreeli ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.”
17 Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ilé Josẹfu: fún Efraimu àti Manase pé, “Lóòtítọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára. Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo. 18 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbó jẹ́ tiyín pẹ̀lú. Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátápátá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kenaani ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, síbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde.”
Pínpín ilẹ̀ tí ó kù
18 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, 2 ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.
3 Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín? 4 Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojú wo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá. 5 Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. 6 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. 7 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”
8 Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.” 9 Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo.
10 Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.
Ìpín ti ẹ̀yà Benjamini
11 Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu:
12 Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni. 13 Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi, (èyí ni Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni
14 Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.
15 Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa. 16 Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá Àfonífojì Refaimu O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli. 17 Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni. 18 Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. 19 Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù.
20 Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.
Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sààmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn.
21 Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:
Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi, 22 Beti-Araba, Ṣemaraimu, Beteli, 23 Affimu, Para, Ofira 24 Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.
25 Gibeoni, Rama, Beeroti, 26 Mispa, Kefira, Mosa, 27 Rekemu, Irpeeli, Tarala, 28 Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn.
Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.
Ìbí Jesu
2 (A)Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé. 2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.) 3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
4 (B)Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe, 5 láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. 6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. 7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti àwọn angẹli
8 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. 9 (C)Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 11 (D)Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. 12 (E)Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
14 (F)“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,
Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”
15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”
16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. 17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. 18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. 19 (G)Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀. 20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.
A gbé Jesu kalẹ̀ nínú Tẹmpili
21 (H)Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.
22 (I)Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa 23 (J)(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), 24 àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.